Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹgba kọ̀ọ̀kan tí Olúwa bá gbé lé wọn pẹ̀lú ọ̀pá ìjẹníyà rẹ̀ yóò jẹ́ ti ṣaworo àti ti dùùrù, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń bá wọn jà lójú ogun pẹ̀lú ìkùùkuu láti apá rẹ̀.

Isaiah 30:32 in English

Isaiah 30:32 · Berean Standard Bible

And with every stroke of the rod of punishment * that the LORD brings down on them, the tambourines and lyres will sound as He battles with weapons brandished.

Context

30Olúwa yóò jẹ́ kí wọn ó gbọ́ ohùn ògo rẹ̀ yóò sì jẹ́ kí wọ́n rí apá rẹ̀ tí ó ń bọ̀ wálẹ̀ pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti iná ajónirun, pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná, àrá àti yìnyín. 31Ohùn Olúwa yóò fọ́ Asiria túútúú, pẹ̀lú ọ̀pá aládé rẹ̀ ni yóò lù wọ́n bolẹ̀. 32Ẹgba kọ̀ọ̀kan tí Olúwa bá gbé lé wọn pẹ̀lú ọ̀pá ìjẹníyà rẹ̀ yóò jẹ́ ti ṣaworo àti ti dùùrù, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń bá wọn jà lójú ogun pẹ̀lú ìkùùkuu láti apá rẹ̀. 33A ti tọ́jú Tofeti sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́, a ti tọ́jú rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba. Ojú ààrò rẹ̀ ni a ti gbẹ́ jì tí ó sì fẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iná àti igi ìdáná; èémí Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìṣàn sulfuru ń jó ṣe mú un gbiná.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.