Isaiah 30:31
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ohùn Olúwa yóò fọ́ Asiria túútúú, pẹ̀lú ọ̀pá aládé rẹ̀ ni yóò lù wọ́n bolẹ̀.
Isaiah 30:31 in English
Isaiah 30:31 · Berean Standard Bible
For Assyria will be shattered at the voice of the LORD; He will strike them with His scepter.
Context
29Ẹ̀yin ó sì kọrin
gẹ́gẹ́ bí i ti alẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe àjọyọ̀ àpéjọ mímọ́,
ọkàn yín yóò yọ̀
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ènìyàn gòkè lọ pẹ̀lú fèrè
sí orí òkè Olúwa,
àní sí àpáta Israẹli. 30Olúwa yóò jẹ́ kí wọn ó gbọ́ ohùn ògo rẹ̀
yóò sì jẹ́ kí wọ́n rí apá rẹ̀ tí ó ń bọ̀ wálẹ̀
pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti iná ajónirun,
pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná, àrá àti yìnyín. 31Ohùn Olúwa yóò fọ́ Asiria túútúú,
pẹ̀lú ọ̀pá aládé rẹ̀ ni yóò lù wọ́n bolẹ̀. 32Ẹgba kọ̀ọ̀kan tí Olúwa bá gbé lé wọn
pẹ̀lú ọ̀pá ìjẹníyà rẹ̀
yóò jẹ́ ti ṣaworo àti ti dùùrù,
gẹ́gẹ́ bí ó ti ń bá wọn jà lójú ogun
pẹ̀lú ìkùùkuu láti apá rẹ̀. 33A ti tọ́jú Tofeti sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́,
a ti tọ́jú rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba.
Ojú ààrò rẹ̀ ni a ti gbẹ́ jì tí ó sì fẹ̀,
pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iná àti igi ìdáná;
èémí Olúwa,
gẹ́gẹ́ bí ìṣàn sulfuru ń jó ṣe mú un gbiná.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.