Isaiah 30:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n ààbò Farao yóò jásí ìtìjú fún un yín, òjìji Ejibiti yóò mú àbùkù bá a yín.
Isaiah 30:3 in English
Isaiah 30:3 · Berean Standard Bible
But Pharaoh’s protection will become your shame, and the refuge of Egypt’s shade your disgrace.
Context
1“Ègbé ni àwọn ọmọ fún orílẹ̀-èdè alágídí,”
ni Olúwa wí,
“Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi,
tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi,
tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀; 2tí wọ́n lọ sí Ejibiti
láìṣe fún mi,
tí ó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Farao fún ààbò,
sí òjìji Ejibiti fún ibi ìsádi. 3Ṣùgbọ́n ààbò Farao yóò jásí ìtìjú fún un yín,
òjìji Ejibiti yóò mú àbùkù bá a yín. 4Bí àwọn olórí rẹ tilẹ̀ wà ní Ṣoani,
tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé sí Hanisi, 5gbogbo wọn ni a ó dójútì,
nítorí àwọn ènìyàn kan tí kò wúlò fún wọn,
tí kò mú ìrànlọ́wọ́ tàbí àǹfààní wá,
bí kò ṣe àbùkù àti ìdójúti ni.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.