Isaiah 30:1
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ègbé ni àwọn ọmọ fún orílẹ̀-èdè alágídí,” ni Olúwa wí, “Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi, tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi, tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀;
Isaiah 30:1 in English
Isaiah 30:1 · Berean Standard Bible
“Woe to the rebellious children,” declares the LORD, “to those who carry out a plan that is not Mine, who form an alliance, but against My will, heaping up sin upon sin.
Context
1“Ègbé ni àwọn ọmọ fún orílẹ̀-èdè alágídí,”
ni Olúwa wí,
“Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi,
tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi,
tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀; 2tí wọ́n lọ sí Ejibiti
láìṣe fún mi,
tí ó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Farao fún ààbò,
sí òjìji Ejibiti fún ibi ìsádi. 3Ṣùgbọ́n ààbò Farao yóò jásí ìtìjú fún un yín,
òjìji Ejibiti yóò mú àbùkù bá a yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.