Isaiah 29:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ, yóò dàbí yanrìn kíkúnná, agbo àwọn aláìláàánú bí ìyàngbò tí a fẹ́ dànù. Lójijì, ní ìṣẹ́jú kan,
Isaiah 29:5 in English
Isaiah 29:5 · Berean Standard Bible
But your many foes will be like fine dust, the multitude of the ruthless like blowing chaff. Then suddenly, in an instant,
Context
3Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo,
Èmi yóò sì fi ilé ìṣọ́ yí ọ ká,
Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdó ti ni mi dojúkọ ọ́. 4Ní ìrẹ̀sílẹ̀, ìwọ ó sì máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá;
ọ̀rọ̀ rẹ yóò sì máa kùn jáde láti inú erùpẹ̀.
Ohun rẹ yóò máa jáde bí i ti ẹnìkan tó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ láti ilẹ̀ jáde wá,
láti inú erùpẹ̀ ni ohùn rẹ
yóò máa wá wúyẹ́wúyẹ́. 5Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ, yóò dàbí yanrìn kíkúnná,
agbo àwọn aláìláàánú bí ìyàngbò tí a fẹ́ dànù.
Lójijì, ní ìṣẹ́jú kan, 6Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò wá
pẹ̀lú àrá àti ilẹ̀-rírì àti ariwo ńlá,
àti ẹ̀fúùfù líle àti iná ajónirun. 7Lẹ́yìn náà,
ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tí gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó bá Arieli jà,
tí ó dojú ìjà kọ òun àti ilé olódi rẹ̀
tí ó sì dó tì í,
yóò dàbí ẹni pé nínú àlá,
bí ìran ní òru
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.