Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn náà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tí gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó bá Arieli jà, tí ó dojú ìjà kọ òun àti ilé olódi rẹ̀ tí ó sì dó tì í, yóò dàbí ẹni pé nínú àlá, bí ìran ní òru

Isaiah 29:7 in English

Isaiah 29:7 · Berean Standard Bible

All the many nations going out to battle against Ariel— even all who war against her, laying siege and attacking her— will be like a dream, like a vision in the night,

Context

5Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ, yóò dàbí yanrìn kíkúnná, agbo àwọn aláìláàánú bí ìyàngbò tí a fẹ́ dànù. Lójijì, ní ìṣẹ́jú kan, 6Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò wá pẹ̀lú àrá àti ilẹ̀-rírì àti ariwo ńlá, àti ẹ̀fúùfù líle àti iná ajónirun. 7Lẹ́yìn náà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tí gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó bá Arieli jà, tí ó dojú ìjà kọ òun àti ilé olódi rẹ̀ tí ó sì dó tì í, yóò dàbí ẹni pé nínú àlá, bí ìran ní òru 8àti bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa ń lá àlá pé òun ń jẹun, ṣùgbọ́n ó jí, ebi rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀; tàbí bí ìgbà tí ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mu omi, ṣùgbọ́n nígbà tí ó jí, sì wò ó, ó dákú, òǹgbẹ sì ń gbẹ ọkàn rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè tí ń bá òkè Sioni jà. 9Ẹ bẹ̀rù kí ẹnu kí ó yà yín, ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ má sì ríran; ẹ mutí yó kì í ṣe ọtí wáìnì, ẹ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n, ṣùgbọ́n kì í ṣe ti ọtí líle.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.