Isaiah 28:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo orí tábìlì ni ó kún fún èébì kò sì ṣí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin.
Isaiah 28:8 in English
Isaiah 28:8 · Berean Standard Bible
For all their tables are covered with vomit; there is not a place without filth.
Context
6Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo
fún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́ ìdájọ́
àti orísun agbára
fún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padà ní ẹnu ibodè. 7Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí wáìnì
wọ́n pòòrì fún ọtí líle,
àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí líle
wọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnì
wọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí líle,
wọ́n ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran,
wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá. 8Gbogbo orí tábìlì ni ó kún fún èébì
kò sì ṣí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin. 9“Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́?
Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìròyìn in rẹ̀ fún?
Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú wọn,
sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú. 10Nítorí tí í ṣe: báyìí ni orí,
ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe,
àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ;
díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.