Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí wáìnì wọ́n pòòrì fún ọtí líle, àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí líle wọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnì wọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí líle, wọ́n ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran, wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá.

Isaiah 28:7 in English

Isaiah 28:7 · Berean Standard Bible

These also stagger from wine and stumble from strong drink: Priests and prophets reel from strong drink and are befuddled by wine. They stumble because of strong drink, muddled in their visions and stumbling in their judgments.

Context

5Ní ọjọ́ náà Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò jẹ́ adé tí ó lógo, àti adé tí ó lẹ́wà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù. 6Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo fún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́ ìdájọ́ àti orísun agbára fún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padà ní ẹnu ibodè. 7Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí wáìnì wọ́n pòòrì fún ọtí líle, àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí líle wọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnì wọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí líle, wọ́n ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran, wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá. 8Gbogbo orí tábìlì ni ó kún fún èébì kò sì ṣí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin. 9“Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́? Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìròyìn in rẹ̀ fún? Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú wọn, sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.