Isaiah 28:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efraimu, ni a ó fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
Isaiah 28:3 in English
Isaiah 28:3 · Berean Standard Bible
The majestic crown of Ephraim’s drunkards will be trampled underfoot.
Context
1Ègbé ni fún adé ìgbéraga,
fún àwọn ọ̀mùtí Efraimu,
àti fún ìtànná rírọ, ẹwà ògo rẹ̀,
tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú
àti sí ìlú náà
ìgbéraga àwọn tí ọtí wáìnì ń pa tí a rẹ̀ sílẹ̀. 2Kíyèsi i, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le, tí ó sì lágbára,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ yìnyín àti bí ìjì apanirun,
gẹ́gẹ́ bí àrọ̀dá òjò àti òjò tí ó mú ìkún omi wá,
òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀. 3Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efraimu,
ni a ó fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀. 4Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀,
tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú,
yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkórè
bí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ rẹ̀,
òun a sì mì ín. 5Ní ọjọ́ náà Olúwa àwọn ọmọ-ogun
yóò jẹ́ adé tí ó lógo,
àti adé tí ó lẹ́wà
fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.