Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, tí ń jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jerusalẹmu.

Isaiah 28:14 in English

Isaiah 28:14 · Berean Standard Bible

Therefore hear the word of the LORD, O scoffers who rule this people in Jerusalem.

Context

12àwọn tí ó sọ fún wí pé, “Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”; àti pé, “Èyí ni ibi ìsinmi”; ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sílẹ̀. 13Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa sí wọn yóò di pé, ṣe èyí, ṣe ìyẹn, àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ; díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubú sẹ́yìn, wọn yóò fi ara pa, wọn yóò bọ́ sínú okùn a ó sì gbá wọn mú. 14Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, tí ń jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jerusalẹmu. 15Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀, pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn. Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá, kò le kàn wá lára, nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o wa àti àìṣòótọ́ ibi ìpamọ́ wa.” 16Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “Kíyèsi i, èmi gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Sioni, òkúta tí a dánwò, òkúta igun ilé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájú; ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé kì yóò ní ìfòyà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.