Isaiah 28:16
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “Kíyèsi i, èmi gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Sioni, òkúta tí a dánwò, òkúta igun ilé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájú; ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé kì yóò ní ìfòyà.
Isaiah 28:16 in English
Isaiah 28:16 · Berean Standard Bible
So this is what the Lord GOD says: “See, I lay a stone in Zion, a tested stone, a precious cornerstone, a sure foundation; the one who believes will never be shaken.*
Context
14Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,
tí ń jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jerusalẹmu. 15Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀,
pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn.
Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá,
kò le kàn wá lára,
nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o wa
àti àìṣòótọ́ ibi ìpamọ́ wa.” 16Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“Kíyèsi i, èmi gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Sioni, òkúta tí a dánwò,
òkúta igun ilé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájú;
ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé
kì yóò ní ìfòyà. 17Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òsùwọ̀n
àti òdodo òjé òsùwọ̀n;
yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́,
omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tí
ẹ ń fi ara pamọ́ sí mọ́lẹ̀. 18Májẹ̀mú yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fa igi lé;
àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró.
Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá,
a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.