Isaiah 28:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa sí wọn yóò di pé, ṣe èyí, ṣe ìyẹn, àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ; díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubú sẹ́yìn, wọn yóò fi ara pa, wọn yóò bọ́ sínú okùn a ó sì gbá wọn mú.
Isaiah 28:13 in English
Isaiah 28:13 · Berean Standard Bible
Then the word of the LORD to them will become: “Order on order, order on order, line on line, line on line; a little here, a little there,” so that they will go stumbling backward and will be injured, ensnared, and captured.
Context
11Ó dára báyìí, pẹ̀lú ètè àjèjì àti ahọ́n àìmọ̀
Ọlọ́run yóò bá àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀ 12àwọn tí ó sọ fún wí pé,
“Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”;
àti pé, “Èyí ni ibi ìsinmi”;
ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sílẹ̀. 13Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa sí wọn yóò di pé,
ṣe èyí, ṣe ìyẹn,
àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ;
díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn,
bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubú sẹ́yìn,
wọn yóò fi ara pa, wọn yóò bọ́ sínú okùn a ó sì gbá wọn mú. 14Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,
tí ń jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jerusalẹmu. 15Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀,
pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn.
Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá,
kò le kàn wá lára,
nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o wa
àti àìṣòótọ́ ibi ìpamọ́ wa.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.