Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru; ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ. Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.

Isaiah 26:9 in English

Isaiah 26:9 · Berean Standard Bible

My soul longs for You in the night; indeed, my spirit seeks You at dawn.* For when Your judgments come upon the earth, the people of the world learn righteousness.

Context

7Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú, ìwọ tó dúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà àwọn olódodo ṣe geere. 8Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹ àwa dúró dè ọ́; orúkọ rẹ àti òkìkí rẹ àwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́. 9Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru; ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ. Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo. 10Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn ìkà wọn kò kọ́ láti sọ òdodo; kódà ní ilẹ̀ àwọn tí ó dúró ṣinṣin wọ́n tẹ̀síwájú láti máa ṣe ibi wọn kò sì ka ọláńlá Olúwa sí. 11Olúwa, ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ṣùgbọ́n àwọn kò rí i. Jẹ́ kí wọ́n rí ìtara rẹ fún àwọn ènìyàn rẹ kí ojú kí ó tì wọ́n; jẹ́ kí iná tí a fi pamọ́ fún àwọn ọ̀tá rẹ jó wọn run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.