Isaiah 26:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú, ìwọ tó dúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà àwọn olódodo ṣe geere.
Isaiah 26:7 in English
Isaiah 26:7 · Berean Standard Bible
The path of the righteous is level; You clear a straight path for the upright.
Context
5Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀
ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀;
ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹsẹ
ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀. 6Ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀
ẹsẹ̀ aninilára n nì,
ipasẹ̀ àwọn òtòṣì. 7Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú,
ìwọ tó dúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà
àwọn olódodo ṣe geere. 8Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹ
àwa dúró dè ọ́;
orúkọ rẹ àti òkìkí rẹ
àwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́. 9Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru;
ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ.
Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé
àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.