Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọn yóò na ọwọ́ wọn jáde nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lúwẹ̀ẹ́. Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ní ọwọ́ wọn.

Isaiah 25:11 in English

Isaiah 25:11 · Berean Standard Bible

He will spread out his hands within it, as a swimmer spreads his arms to swim. His pride will be brought low, despite * the skill of his hands.

Context

9Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé, “Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa; àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là. Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e, ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.” 10Ọwọ́ Olúwa yóò sinmi lé orí òkè yìí ṣùgbọ́n a ó tẹ Moabu mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti gún koríko mọ́lẹ̀ di ajílẹ̀. 11Wọn yóò na ọwọ́ wọn jáde nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ rẹ̀ jáde láti lúwẹ̀ẹ́. Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ní ọwọ́ wọn. 12Òun yóò sì bi gbogbo ògiri gíga alágbára yín lulẹ̀ wọn yóò sì wà nílẹ̀, Òun yóò sì mú wọn wá si ilẹ̀, àní sí erùpẹ̀ lásán.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.