Isaiah 25:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọwọ́ Olúwa yóò sinmi lé orí òkè yìí ṣùgbọ́n a ó tẹ Moabu mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti gún koríko mọ́lẹ̀ di ajílẹ̀.
Isaiah 25:10 in English
Isaiah 25:10 · Berean Standard Bible
For the hand of the LORD will rest on this mountain. But Moab will be trampled in his place as straw is trodden into the dung pile.
Context
8Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé.
Olúwa Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù,
kúrò ní ojú gbogbo wọn,
Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò
ní gbogbo ilẹ̀ ayé.
Olúwa ni ó ti sọ ọ́. 9Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé,
“Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa;
àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là.
Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e,
ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.” 10Ọwọ́ Olúwa yóò sinmi lé orí òkè yìí
ṣùgbọ́n a ó tẹ Moabu mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀;
gẹ́gẹ́ bí a ti gún koríko mọ́lẹ̀ di ajílẹ̀. 11Wọn yóò na ọwọ́ wọn jáde nínú rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ rẹ̀
jáde láti lúwẹ̀ẹ́.
Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀
bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ní ọwọ́ wọn. 12Òun yóò sì bi gbogbo ògiri gíga alágbára yín lulẹ̀
wọn yóò sì wà nílẹ̀,
Òun yóò sì mú wọn wá si ilẹ̀,
àní sí erùpẹ̀ lásán.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.