Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà ní ìlà-oòrùn ẹ fi ògo fún Olúwa; gbé orúkọ Olúwa ga, àní Ọlọ́run Israẹli, ní àwọn erékùṣù ti inú Òkun.

Isaiah 24:15 in English

Isaiah 24:15 · Berean Standard Bible

Therefore glorify the LORD in the east. Extol the name of the LORD, the God of Israel in the islands * of the sea.

Context

13Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí ní orí ilẹ̀ ayé àti láàrín àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a lu igi olifi, tàbí gẹ́gẹ́ bí i pàǹtí tí ó ṣẹ́kù lẹ́yìn tí a kórè èso tán. 14Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀; láti ìwọ̀-oòrùn ni wọn yóò ti polongo ọláńlá Olúwa. 15Nítorí náà ní ìlà-oòrùn ẹ fi ògo fún Olúwa; gbé orúkọ Olúwa ga, àní Ọlọ́run Israẹli, ní àwọn erékùṣù ti inú Òkun. 16Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin; “Ògo ni fún olódodo n nì.” Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Mo ṣègbé, mo ṣègbé! “Ègbé ni fún mi! Alárékérekè dalẹ̀! Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!” 17Ìpayà, isà òkú, àti ìdẹ̀kùn ń dúró dè ọ́, ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.