Isaiah 24:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìpayà, isà òkú, àti ìdẹ̀kùn ń dúró dè ọ́, ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé.
Isaiah 24:17 in English
Isaiah 24:17 · Berean Standard Bible
Terror and pit and snare await you, O dweller of the earth.
Context
15Nítorí náà ní ìlà-oòrùn ẹ fi ògo fún Olúwa;
gbé orúkọ Olúwa ga, àní
Ọlọ́run Israẹli,
ní àwọn erékùṣù ti inú Òkun. 16Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin;
“Ògo ni fún olódodo n nì.”
Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Mo ṣègbé, mo ṣègbé!
“Ègbé ni fún mi!
Alárékérekè dalẹ̀!
Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!” 17Ìpayà, isà òkú, àti ìdẹ̀kùn ń dúró dè ọ́,
ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé. 18Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá nítorí ariwo ìpayà
yóò ṣubú sínú ihò,
ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yọ́ jáde nínú ihò
ni ìdẹ̀kùn yóò gbámú.
Ibodè ọ̀run ti wà ní ṣíṣí sílẹ̀,
ìpìlẹ̀ ayé mì tìtì. 19Ilẹ̀ ayé ti fọ́
ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù,
a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.