Isaiah 22:16
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín yìí àti pé ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ láti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín yìí, tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gíga tí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta?
Isaiah 22:16 in English
Isaiah 22:16 · Berean Standard Bible
What are you doing here, and who authorized you to carve out a tomb for yourself here—to chisel your tomb in the height and cut your resting place in the rock?
Context
14Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mí mọ̀ létí ì mi: “Títí di ọjọ́ ikú yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 15Èyí ni ohun tí Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,
“Lọ, sọ fún ìríjú yìí pé,
fún Ṣebna, ẹni tí ààfin wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. 16Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín yìí àti pé
ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ
láti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín yìí,
tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gíga
tí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta? 17“Kíyèsára, Olúwa fẹ́ gbá ọ mú gírígírí
kí ó sì jù ọ́ nù, ìwọ ọkùnrin alágbára. 18Òun yóò ká ọ rúgúdù bí i òkìtì
yóò sì sọ ọ́ sí orílẹ̀-èdè ńlá kan.
Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí
àti níbẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn kẹ̀kẹ́ ogun
àràmọ̀ǹdà rẹ yóò wà—
ìwọ di ìtìjú sí ilé ọ̀gá rẹ!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.