Isaiah 22:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ni ohun tí Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Lọ, sọ fún ìríjú yìí pé, fún Ṣebna, ẹni tí ààfin wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.
Isaiah 22:15 in English
Isaiah 22:15 · Berean Standard Bible
This is what the Lord GOD of Hosts says: “Go, say to Shebna, the steward in charge of the palace:
Context
13Ṣùgbọ́n wò ó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wà;
màlúù pípa àti àgùntàn pípa,
ẹran jíjẹ àti ọtí wáìnì mímu!
Ẹ̀yin wí pé, “Jẹ́ kí a jẹ kí a mu,
nítorí pé lọ́la àwa ó kú!” 14Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mí mọ̀ létí ì mi: “Títí di ọjọ́ ikú yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 15Èyí ni ohun tí Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,
“Lọ, sọ fún ìríjú yìí pé,
fún Ṣebna, ẹni tí ààfin wà ní ìkáwọ́ rẹ̀. 16Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín yìí àti pé
ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ
láti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín yìí,
tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gíga
tí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta? 17“Kíyèsára, Olúwa fẹ́ gbá ọ mú gírígírí
kí ó sì jù ọ́ nù, ìwọ ọkùnrin alágbára.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.