Isaiah 21:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n tẹ́ tábìlì, wọ́n tẹ́ ẹní àtẹ́ẹ̀ká, wọ́n jẹ, wọ́n mu! Dìde nílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ-aládé, ẹ fi òróró kún asà yín!
Isaiah 21:5 in English
Isaiah 21:5 · Berean Standard Bible
They prepare a table, they lay out a carpet, they eat, they drink! Rise up, O princes, oil the shields!
Context
3Pẹ̀lú èyí, ìrora mu mi lára gírígírí,
ìrora gbá mi mú, gẹ́gẹ́ bí i ti
obìnrin tí ń rọbí,
mo ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nítorí ohun tí mo gbọ́,
ọkàn mi pòruurù nípa ohun tí mo rí. 4Ọkàn mí dàrú,
ẹ̀rù mú jìnnìjìnnì bá mi,
ìmọ́lẹ̀ tí mo ti ń fẹ́ ẹ́ rí
ti wá di ìpayà fún mi. 5Wọ́n tẹ́ tábìlì,
wọ́n tẹ́ ẹní àtẹ́ẹ̀ká,
wọ́n jẹ, wọ́n mu!
Dìde nílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ-aládé,
ẹ fi òróró kún asà yín! 6Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:
“Lọ, kí o bojúwòde
kí o sì wá sọ ohun tí ó rí. 7Nígbà tí ó bá rí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun
àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin,
àwọn tó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
tàbí àwọn tí ó gun ìbákasẹ,
jẹ́ kí ó múra sílẹ̀,
àní ìmúra gidigidi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.