Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Pẹ̀lú èyí, ìrora mu mi lára gírígírí, ìrora gbá mi mú, gẹ́gẹ́ bí i ti obìnrin tí ń rọbí, mo ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nítorí ohun tí mo gbọ́, ọkàn mi pòruurù nípa ohun tí mo rí.

Isaiah 21:3 in English

Isaiah 21:3 · Berean Standard Bible

Therefore my body is filled with anguish. Pain grips me, like the pains of a woman in labor. I am bewildered to hear, I am dismayed to see.

Context

1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan aginjù lẹ́bàá Òkun. Gẹ́gẹ́ bí ìjì líle ti í jà kọjá ní gúúsù, akógunjàlú kan wá láti aginjù, láti ilẹ̀ ìpayà. 2Ìran tí a ń fojú ṣọ́nà fún ni a ti fihàn mí ọlọ̀tẹ̀ ti tu àṣírí, fọ́lé fọ́lé ti kẹ́rù. Elamu kojú ìjà! Media ti tẹ̀gùn! Èmi yóò mú gbogbo ìpayínkeke dópin, ni ó búra. 3Pẹ̀lú èyí, ìrora mu mi lára gírígírí, ìrora gbá mi mú, gẹ́gẹ́ bí i ti obìnrin tí ń rọbí, mo ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nítorí ohun tí mo gbọ́, ọkàn mi pòruurù nípa ohun tí mo rí. 4Ọkàn mí dàrú, ẹ̀rù mú jìnnìjìnnì bá mi, ìmọ́lẹ̀ tí mo ti ń fẹ́ ẹ́ rí ti wá di ìpayà fún mi. 5Wọ́n tẹ́ tábìlì, wọ́n tẹ́ ẹní àtẹ́ẹ̀ká, wọ́n jẹ, wọ́n mu! Dìde nílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ-aládé, ẹ fi òróró kún asà yín!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.