Isaiah 21:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìran tí a ń fojú ṣọ́nà fún ni a ti fihàn mí ọlọ̀tẹ̀ ti tu àṣírí, fọ́lé fọ́lé ti kẹ́rù. Elamu kojú ìjà! Media ti tẹ̀gùn! Èmi yóò mú gbogbo ìpayínkeke dópin, ni ó búra.
Isaiah 21:2 in English
Isaiah 21:2 · Berean Standard Bible
A dire vision is declared to me: “The traitor still betrays, and the destroyer still destroys. Go up, O Elam! Lay siege, O Media! I will put an end to all her groaning.”
Context
1Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan aginjù lẹ́bàá Òkun.
Gẹ́gẹ́ bí ìjì líle ti í jà kọjá ní gúúsù,
akógunjàlú kan wá láti aginjù,
láti ilẹ̀ ìpayà. 2Ìran tí a ń fojú ṣọ́nà fún ni a ti fihàn mí
ọlọ̀tẹ̀ ti tu àṣírí, fọ́lé fọ́lé ti kẹ́rù.
Elamu kojú ìjà! Media ti tẹ̀gùn!
Èmi yóò mú gbogbo ìpayínkeke dópin,
ni ó búra. 3Pẹ̀lú èyí, ìrora mu mi lára gírígírí,
ìrora gbá mi mú, gẹ́gẹ́ bí i ti
obìnrin tí ń rọbí,
mo ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nítorí ohun tí mo gbọ́,
ọkàn mi pòruurù nípa ohun tí mo rí. 4Ọkàn mí dàrú,
ẹ̀rù mú jìnnìjìnnì bá mi,
ìmọ́lẹ̀ tí mo ti ń fẹ́ ẹ́ rí
ti wá di ìpayà fún mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.