Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Lọ, kí o bojúwòde kí o sì wá sọ ohun tí ó rí.

Isaiah 21:6 in English

Isaiah 21:6 · Berean Standard Bible

For this is what the Lord says to me: “Go, post a lookout and have him report what he sees.

Context

4Ọkàn mí dàrú, ẹ̀rù mú jìnnìjìnnì bá mi, ìmọ́lẹ̀ tí mo ti ń fẹ́ ẹ́ rí ti wá di ìpayà fún mi. 5Wọ́n tẹ́ tábìlì, wọ́n tẹ́ ẹní àtẹ́ẹ̀ká, wọ́n jẹ, wọ́n mu! Dìde nílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ-aládé, ẹ fi òróró kún asà yín! 6Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Lọ, kí o bojúwòde kí o sì wá sọ ohun tí ó rí. 7Nígbà tí ó bá rí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin, àwọn tó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí àwọn tí ó gun ìbákasẹ, jẹ́ kí ó múra sílẹ̀, àní ìmúra gidigidi.” 8Òun sì kígbe pé, kìnnìún kan, “Láti ọjọ́ dé ọjọ́, olúwa mi, mo dúró lórí ilé ìṣọ́ ní ọ̀sán, a sì fi mí ìṣọ́ mi ní gbogbo òru.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.