Isaiah 19:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo omi inú odò ni yóò gbẹ, gbogbo ilẹ̀ àyíká odò ni yóò gbẹ tí yóò sì sáàpá.
Isaiah 19:5 in English
Isaiah 19:5 · Berean Standard Bible
The waters of the Nile will dry up, and the riverbed will be parched and empty.
Context
3Àwọn ará Ejibiti yóò sọ ìrètí nù,
èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo;
wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀,
àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀. 4Èmi yóò fi Ejibiti lé agbára
àwọn ìkà amúnisìn lọ́wọ́,
ọba aláìláàánú ni yóò jẹ ọba lé wọn lórí,”
ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 5Gbogbo omi inú odò ni yóò gbẹ,
gbogbo ilẹ̀ àyíká odò ni yóò gbẹ tí yóò sì sáàpá. 6Adágún omi yóò sì di rírùn;
àwọn odò ilẹ̀ Ejibiti yóò máa dínkù
wọn yóò sì gbẹ.
Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ, 7àwọn igi ipadò Naili pẹ̀lú,
tí ó wà ní orísun odò,
gbogbo oko tí a dá sí ipadò Naili
yóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànù
tí kò sì ní sí mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.