Isaiah 19:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àwọn igi ipadò Naili pẹ̀lú, tí ó wà ní orísun odò, gbogbo oko tí a dá sí ipadò Naili yóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànù tí kò sì ní sí mọ́.
Isaiah 19:7 in English
Isaiah 19:7 · Berean Standard Bible
The bulrushes by the Nile, by the mouth of the river, and all the fields sown along the Nile, will wither, blow away, and be no more.
Context
5Gbogbo omi inú odò ni yóò gbẹ,
gbogbo ilẹ̀ àyíká odò ni yóò gbẹ tí yóò sì sáàpá. 6Adágún omi yóò sì di rírùn;
àwọn odò ilẹ̀ Ejibiti yóò máa dínkù
wọn yóò sì gbẹ.
Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ, 7àwọn igi ipadò Naili pẹ̀lú,
tí ó wà ní orísun odò,
gbogbo oko tí a dá sí ipadò Naili
yóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànù
tí kò sì ní sí mọ́. 8Àwọn apẹja yóò sọkún kíkorò,
àti gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú odò;
odò náà yóò sì máa rùn. 9Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminú
àwọn ahunṣọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.