Isaiah 14:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Babeli pé, báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin! Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí!
Isaiah 14:4 in English
Isaiah 14:4 · Berean Standard Bible
you will sing this song of contempt against the king of Babylon: How the oppressor has ceased, and how his fury * has ended!
Context
2Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbà wọ́n
wọn yóò sì mú wọn wá sí ààyè e wọn.
Ilé Israẹli yóò gba àwọn orílẹ̀-èdè
gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin
ní ilẹ̀ Olúwa.
Wọn yóò kó àwọn akónilẹ́rú wọn ní ìgbèkùn
wọn yóò sì jẹ ọba lórí àwọn amúnisìn wọn. 3Ní ọjọ́ tí Olúwa yóò fi ìtura fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà, 4ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Babeli pé,
báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin!
Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí! 5Olúwa ti dá ọ̀pá ìkà náà,
ọ̀pá àwọn aláṣẹ, 6èyí tí ó ti lu àwọn ènìyàn bolẹ̀
pẹ̀lú ti kò dáwọ́ dúró,
nínú ìrunú ni ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè
pẹ̀lú ìgbónára tí kò lópin.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.