Isaiah 13:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ hu, nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ tòsí, yóò sì wá gẹ́gẹ́ bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Alágbára jùlọ.
Isaiah 13:6 in English
Isaiah 13:6 · Berean Standard Bible
Wail, for the Day of the LORD is near; it will come as destruction from the Almighty.*
Context
4Gbọ́ ohùn kan ní àwọn orí òkè,
gẹ́gẹ́ bí i ti ogunlọ́gọ̀ ènìyàn.
Gbọ́ ìdàrúdàpọ̀ láàrín àwọn ìjọba,
gẹ́gẹ́ bí i ti ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè!
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti kó ogun rẹ̀ jọ
àwọn jagunjagun fún ogun. 5Wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn réré,
láti ìpẹ̀kun ọ̀run wá
Olúwa pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ìbínú rẹ̀,
láti pa gbogbo orílẹ̀-èdè náà run. 6Ẹ hu, nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ tòsí,
yóò sì wá gẹ́gẹ́ bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Alágbára jùlọ. 7Nítorí èyí, gbogbo ọwọ́ ni yóò rọ,
ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò rẹ̀wẹ̀sì. 8Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú,
ìrora àti ìpayínkeke yóò dìwọ́n mú,
wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí.
Ẹnìkínní yóò wo ẹnìkejì rẹ̀ pẹ̀lú ìpayà
ojú wọn á sì gbinájẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.