Isaiah 10:24
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, báyìí ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Sioni, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Asiria, tí ó ń fi ọ̀pá lù yín, tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tì yín bí Ejibiti ti ṣe.
Isaiah 10:24 in English
Isaiah 10:24 · Berean Standard Bible
Therefore this is what the Lord GOD of Hosts says: “O My people who dwell in Zion, do not fear Assyria, who strikes you with a rod and lifts his staff against you as the Egyptians did.
Context
22Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ Israẹli dàbí yanrìn ní Òkun,
ẹni díẹ̀ ni yóò padà.
A ti pàṣẹ ìparun,
àkúnwọ́sílẹ̀ àti òdodo. 23Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú un ṣẹ,
ìparun tí a ti pàṣẹ rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ náà. 24Nítorí náà, báyìí ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,
“Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Sioni,
ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Asiria,
tí ó ń fi ọ̀pá lù yín,
tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tì yín bí
Ejibiti ti ṣe. 25Láìpẹ́, ìbínú mi sí i yín yóò wá sí òpin
n ó sì dojú ìrunú mi kọ wọ́n, fún ìparun wọn.” 26Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò nà wọ́n ní ẹgba.
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe lu Midiani ní òkè Orebu,
yóò sì gbé ọ̀pá rẹ̀ lé orí omi
gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Ejibiti.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.