Isaiah 10:23
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú un ṣẹ, ìparun tí a ti pàṣẹ rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ náà.
Isaiah 10:23 in English
Isaiah 10:23 · Berean Standard Bible
For the Lord GOD of Hosts will carry out the destruction decreed upon the whole land.*
Context
21Àwọn ìyókù yóò padà, àwọn ìyókù ti Jakọbu
yóò padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Alágbára. 22Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ Israẹli dàbí yanrìn ní Òkun,
ẹni díẹ̀ ni yóò padà.
A ti pàṣẹ ìparun,
àkúnwọ́sílẹ̀ àti òdodo. 23Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú un ṣẹ,
ìparun tí a ti pàṣẹ rẹ̀ lórí gbogbo ilẹ̀ náà. 24Nítorí náà, báyìí ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,
“Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Sioni,
ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Asiria,
tí ó ń fi ọ̀pá lù yín,
tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tì yín bí
Ejibiti ti ṣe. 25Láìpẹ́, ìbínú mi sí i yín yóò wá sí òpin
n ó sì dojú ìrunú mi kọ wọ́n, fún ìparun wọn.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.