Isaiah 10:18
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo ẹwà igbó o rẹ̀, àti àwọn pápá ọlọ́ràá gbogbo rẹ̀ ni yóò run pátápátá, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ṣàìsàn ti í ṣòfò dànù.
Isaiah 10:18 in English
Isaiah 10:18 · Berean Standard Bible
The splendor of its forests and orchards, both soul and body, it will completely destroy, as a sickness consumes a man.
Context
16Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
yóò rán ààrùn ìrẹ̀dànù sórí
àwọn akíkanjú jagunjagun,
lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ
gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun. 17Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóò di iná,
Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀wọ́-iná,
ní ọjọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì run
àti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n. 18Gbogbo ẹwà igbó o rẹ̀, àti àwọn pápá ọlọ́ràá
gbogbo rẹ̀ ni yóò run pátápátá,
gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ṣàìsàn ti í ṣòfò dànù. 19Àwọn igi tí yóò kù nínú igbó o rẹ̀
yóò kéré níye,
tí ọ̀dọ́mọdé yóò fi le kọ̀ wọ́n sílẹ̀. 20Ní ọjọ́ náà, àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli,
àwọn tí ó yè ní ilé e Jakọbu,
kò ní gbẹ́kẹ̀lé ẹni náà
tí ó lù wọ́n bolẹ̀,
ṣùgbọ́n ní òtítọ́ yóò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa,
Ẹni Mímọ́ Israẹli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.