Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóò di iná, Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀wọ́-iná, ní ọjọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì run àti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n.

Isaiah 10:17 in English

Isaiah 10:17 · Berean Standard Bible

And the Light of Israel will become a fire, and its Holy One a flame. In a single day it will burn and devour Assyria’s thorns and thistles.

Context

15Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í, tàbí kí ayùn fọ́nnu sí ẹni tí ó ń lò ó? Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè, tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi. 16Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, yóò rán ààrùn ìrẹ̀dànù sórí àwọn akíkanjú jagunjagun, lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun. 17Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóò di iná, Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀wọ́-iná, ní ọjọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì run àti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n. 18Gbogbo ẹwà igbó o rẹ̀, àti àwọn pápá ọlọ́ràá gbogbo rẹ̀ ni yóò run pátápátá, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ṣàìsàn ti í ṣòfò dànù. 19Àwọn igi tí yóò kù nínú igbó o rẹ̀ yóò kéré níye, tí ọ̀dọ́mọdé yóò fi le kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.