Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Orílẹ̀-èdè yín dahoro, a dáná sun àwọn ìlú yín, oko yín ni àwọn àjèjì ti jẹ run lójú ara yín náà, ni gbogbo rẹ̀ ṣòfò bí èyí tí àwọn àjèjì borí rẹ̀.

Isaiah 1:7 in English

Isaiah 1:7 · Berean Standard Bible

Your land is desolate; your cities are burned with fire. Foreigners devour your fields before you— a desolation demolished by strangers.

Context

5Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́? Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe? Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́, gbogbo ọkàn yín sì ti pòruurù. 6Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín dé àtàrí yín kò sí àlàáfíà rárá, àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapa àti ojú egbò, tí a kò nù kúrò tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró. 7Orílẹ̀-èdè yín dahoro, a dáná sun àwọn ìlú yín, oko yín ni àwọn àjèjì ti jẹ run lójú ara yín náà, ni gbogbo rẹ̀ ṣòfò bí èyí tí àwọn àjèjì borí rẹ̀. 8Ọmọbìnrin Sioni ni a fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà, gẹ́gẹ́ bí abà nínú oko ẹ̀gúnsí, àti bí ìlú tí a dó tì. 9Àyàfi bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun bá ṣẹ́ díẹ̀ kù fún wà, a ò bá ti rí bí Sodomu, a ò bá sì ti dàbí Gomorra.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.