Isaiah 1:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín dé àtàrí yín kò sí àlàáfíà rárá, àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapa àti ojú egbò, tí a kò nù kúrò tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró.
Isaiah 1:6 in English
Isaiah 1:6 · Berean Standard Bible
From the sole of your foot to the top of your head, there is no soundness— only wounds and welts and festering sores neither cleansed nor bandaged nor soothed with oil.
Context
4Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀,
àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù,
ìran àwọn aṣebi,
àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́!
Wọn ti kọ Olúwa sílẹ̀
wọn ti gan Ẹni Mímọ́ Israẹli,
wọn sì ti kẹ̀yìn sí i. 5Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́?
Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe?
Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́,
gbogbo ọkàn yín sì ti pòruurù. 6Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín dé àtàrí yín
kò sí àlàáfíà rárá,
àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapa
àti ojú egbò,
tí a kò nù kúrò tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró. 7Orílẹ̀-èdè yín dahoro,
a dáná sun àwọn ìlú yín,
oko yín ni àwọn àjèjì ti jẹ run
lójú ara yín náà,
ni gbogbo rẹ̀ ṣòfò bí èyí tí
àwọn àjèjì borí rẹ̀. 8Ọmọbìnrin Sioni ni a fi sílẹ̀
gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà,
gẹ́gẹ́ bí abà nínú oko ẹ̀gúnsí,
àti bí ìlú tí a dó tì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.