Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Sioni padà, àti àwọn tí ó ronúpìwàdà pẹ̀lú òdodo.

Isaiah 1:27 in English

Isaiah 1:27 · Berean Standard Bible

Zion will be redeemed with justice, her repentant ones with righteousness.

Context

25Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ, èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù, n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò. 26Èmi yóò mú àwọn adájọ́ rẹ bọ̀ sí ipò gẹ́gẹ́ bí i ti àtijọ́, àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ bí i ti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Lẹ́yìn náà ni a ó pè ọ ní ìlú òdodo, ìlú òtítọ́.” 27A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Sioni padà, àti àwọn tí ó ronúpìwàdà pẹ̀lú òdodo. 28Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó parun. Àwọn tí ó bá sì kọ Olúwa sílẹ̀ ni yóò ṣègbé. 29“Ojú yóò tì yín nítorí igi óákù mímọ́ èyí tí ẹ ní inú dídùn sí, a ó kàn yín lábùkù nítorí àwọn ọgbà yìí tí ẹ ti yàn fúnra yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.