Isaiah 1:25
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ, èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù, n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.
Isaiah 1:25 in English
Isaiah 1:25 · Berean Standard Bible
I will turn My hand against you; I will thoroughly purge your dross; I will remove all your impurities.
Context
23Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín,
akẹgbẹ́ àwọn olè,
gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀
wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri.
Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,
ẹjọ́ opó kì í sì í dé iwájú wọn. 24Nítorí náà ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
alágbára kan ṣoṣo tí Israẹli sọ wí pé:
“Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá mi
n ó sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi. 25Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ,
èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù,
n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò. 26Èmi yóò mú àwọn adájọ́ rẹ bọ̀ sí ipò gẹ́gẹ́ bí i ti àtijọ́,
àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ bí i ti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.
Lẹ́yìn náà ni a ó pè ọ ní ìlú òdodo, ìlú òtítọ́.” 27A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Sioni padà,
àti àwọn tí ó ronúpìwàdà pẹ̀lú òdodo.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.