Isaiah 1:29
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ojú yóò tì yín nítorí igi óákù mímọ́ èyí tí ẹ ní inú dídùn sí, a ó kàn yín lábùkù nítorí àwọn ọgbà yìí tí ẹ ti yàn fúnra yín.
Isaiah 1:29 in English
Isaiah 1:29 · Berean Standard Bible
Surely you will be ashamed of the sacred oaks in which you have delighted; you will be embarrassed by the gardens that you have chosen.
Context
27A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Sioni padà,
àti àwọn tí ó ronúpìwàdà pẹ̀lú òdodo. 28Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó parun.
Àwọn tí ó bá sì kọ Olúwa sílẹ̀ ni yóò ṣègbé. 29“Ojú yóò tì yín nítorí igi óákù mímọ́
èyí tí ẹ ní inú dídùn sí,
a ó kàn yín lábùkù nítorí àwọn ọgbà yìí
tí ẹ ti yàn fúnra yín. 30Ẹ ó sì dàbí igi óákù tí ewé rẹ̀ ti rọ,
bí ọgbà tí kò ní omi. 31Alágbára ọkùnrin náà yóò sì dàbí ohun ìdáná,
iṣẹ́ rẹ̀ bí ẹ̀ṣẹ́-iná,
àwọn méjèèjì ni yóò jóná papọ̀,
láìsí ẹni tí yóò lè pa iná yìí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.