Isaiah 1:19
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tí ẹ̀yin bá fẹ́, tí ẹ sì gbọ́rọ̀, ẹ̀yin yóò sì jẹ ojúlówó adùn ilẹ̀ náà.
Isaiah 1:19 in English
Isaiah 1:19 · Berean Standard Bible
If you are willing and obedient, you will eat the best of the land.
Context
17kọ́ láti ṣe rere!
Wá ìdájọ́ òtítọ́,
tu àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú.
Ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,
gbà ẹjọ́ opó rò. 18“Ẹ wá ní ìsinsin yìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàṣàrò,”
ni Olúwa wí.
“Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn,
wọn ó sì funfun bí i yìnyín,
bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀,
wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n òwú. 19Tí ẹ̀yin bá fẹ́, tí ẹ sì gbọ́rọ̀,
ẹ̀yin yóò sì jẹ ojúlówó adùn ilẹ̀ náà. 20Ṣùgbọ́n tí ẹ bá kọ̀ tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀,
idà ni a ó fi pa yín run.”
Nítorí ẹnu Olúwa la ti sọ ọ́. 21Wo bí ìlú òtítọ́ ṣe di àgbèrè!
Ó ti kún fún ìdájọ́ òtítọ́ nígbà kan rí,
òdodo ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí,
ṣùgbọ́n báyìí àwọn apànìyàn!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.