Isaiah 1:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin aláṣẹ Sodomu, tẹ́tí sí òfin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn Gomorra!
Isaiah 1:10 in English
Isaiah 1:10 · Berean Standard Bible
Hear the word of the LORD, you rulers of Sodom; listen to the instruction of our God, you people of Gomorrah!
Context
8Ọmọbìnrin Sioni ni a fi sílẹ̀
gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà,
gẹ́gẹ́ bí abà nínú oko ẹ̀gúnsí,
àti bí ìlú tí a dó tì. 9Àyàfi bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun
bá ṣẹ́ díẹ̀ kù fún wà,
a ò bá ti rí bí Sodomu,
a ò bá sì ti dàbí Gomorra. 10Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa,
ẹ̀yin aláṣẹ Sodomu,
tẹ́tí sí òfin Ọlọ́run wa,
ẹ̀yin ènìyàn Gomorra! 11“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín
kín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi?” ni Olúwa wí.
“Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísun
ti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa,
Èmi kò ní inú dídùn
nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntàn àti ti òbúkọ. 12Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi,
ta ni ó béèrè èyí lọ́wọ́ yín,
gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.