Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi, ta ni ó béèrè èyí lọ́wọ́ yín, gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi?

Isaiah 1:12 in English

Isaiah 1:12 · Berean Standard Bible

When you come to appear before Me, who has required this of you— this trampling of My courts?

Context

10Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin aláṣẹ Sodomu, tẹ́tí sí òfin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn Gomorra! 11“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín kín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi?” ni Olúwa wí. “Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísun ti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa, Èmi kò ní inú dídùn nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntàn àti ti òbúkọ. 12Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi, ta ni ó béèrè èyí lọ́wọ́ yín, gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi? 13Ẹ má mú ọrẹ asán wá mọ́! Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi, oṣù tuntun àti ọjọ́ ìsinmi àti àwọn àpéjọ, Èmi kò lè faradà á, ẹ̀ṣẹ̀ ni àpéjọ yín wọ̀nyí. 14Ayẹyẹ oṣù tuntun yín àti àjọ̀dún tí a yàn, ni ọkàn mi kórìíra. Wọ́n ti di àjàgà sí mi ní ọrùn, Ó sú mi láti fi ara dà wọ́n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.