Isaiah 1:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ má mú ọrẹ asán wá mọ́! Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi, oṣù tuntun àti ọjọ́ ìsinmi àti àwọn àpéjọ, Èmi kò lè faradà á, ẹ̀ṣẹ̀ ni àpéjọ yín wọ̀nyí.
Isaiah 1:13 in English
Isaiah 1:13 · Berean Standard Bible
Bring your worthless offerings no more; your incense is detestable to Me— your New Moons, Sabbaths, and convocations. I cannot endure iniquity in a solemn assembly.
Context
11“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín
kín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi?” ni Olúwa wí.
“Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísun
ti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa,
Èmi kò ní inú dídùn
nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntàn àti ti òbúkọ. 12Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi,
ta ni ó béèrè èyí lọ́wọ́ yín,
gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi? 13Ẹ má mú ọrẹ asán wá mọ́!
Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi,
oṣù tuntun àti ọjọ́ ìsinmi àti àwọn àpéjọ,
Èmi kò lè faradà á, ẹ̀ṣẹ̀ ni àpéjọ yín wọ̀nyí. 14Ayẹyẹ oṣù tuntun yín àti àjọ̀dún tí a yàn,
ni ọkàn mi kórìíra.
Wọ́n ti di àjàgà sí mi ní ọrùn,
Ó sú mi láti fi ara dà wọ́n. 15Nígbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sókè ni àdúrà,
Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín,
kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà,
Èmi kò ni tẹ́tí sí i.
“Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.