Hosea 9:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wòlíì, papọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, ni olùṣọ́ ọ Efraimu. Síbẹ̀ ìdẹ̀kùn dúró dè é ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti ìkórìíra ní ilé Ọlọ́run rẹ̀.
Hosea 9:8 in English
Hosea 9:8 · Berean Standard Bible
The prophet is Ephraim’s watchman, along with my God,* yet the snare of the fowler lies on all his paths. Hostility is in the house of his God!
Context
6Bí wọ́n tilẹ̀ yọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun
Ejibiti yóò kó wọn jọ,
Memfisi yóò sì sin wọ́n.
Ibi ìsọjọ̀ fàdákà wọn ni ẹ̀gún yóò jogún,
Ẹ̀gún yóò bo àpótí ìṣúra fàdákà wọn.
Ẹ̀gún yóò sì bo
gbogbo àgọ́ wọn. 7Àwọn ọjọ́ ìjìyà ń bọ̀;
àwọn ọjọ́ ìṣirò iṣẹ́ ti dé.
Jẹ́ kí Israẹli mọ èyí.
Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀
ìkórìíra yín sì pọ̀ gan an ni.
A ka àwọn wòlíì sí òmùgọ̀,
a ka ẹni ìmísí sí asínwín. 8Wòlíì, papọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,
ni olùṣọ́ ọ Efraimu.
Síbẹ̀ ìdẹ̀kùn dúró dè é ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀
àti ìkórìíra ní ilé Ọlọ́run rẹ̀. 9Wọ́n ti gbilẹ̀ nínú ìwà ìbàjẹ́
gẹ́gẹ́ bí i ọjọ́ Gibeah
Ọlọ́run yóò rántí ìwà búburú wọn
yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 10“Mo rí Israẹli bí èso àjàrà ní aginjù.
Mo rí àwọn baba yín,
bí àkọ́pọ́n nínú igi ọ̀pọ̀tọ́ ní àkọ́so rẹ̀.
Ṣùgbọ́n wọ́n tọ Baali-Peori lọ,
wọ́n yà wọn sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń mú ìtìjú bá ni,
ohun ìríra wọn sì rí gẹ́gẹ́ bí wọn ti fẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.