Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ni ẹ̀yin ó ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún Olúwa?

Hosea 9:5 in English

Hosea 9:5 · Berean Standard Bible

What will you do on the appointed day, on the day of the LORD’s feast?

Context

3Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé Olúwa Efraimu yóò padà sí Ejibiti, yóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ́ ní Asiria. 4Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún Olúwa. Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn. Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀. Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́. Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnra wọn kò ní wá sí orí tẹmpili Olúwa. 5Kí ni ẹ̀yin ó ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún Olúwa? 6Bí wọ́n tilẹ̀ yọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun Ejibiti yóò kó wọn jọ, Memfisi yóò sì sin wọ́n. Ibi ìsọjọ̀ fàdákà wọn ni ẹ̀gún yóò jogún, Ẹ̀gún yóò bo àpótí ìṣúra fàdákà wọn. Ẹ̀gún yóò sì bo gbogbo àgọ́ wọn. 7Àwọn ọjọ́ ìjìyà ń bọ̀; àwọn ọjọ́ ìṣirò iṣẹ́ ti dé. Jẹ́ kí Israẹli mọ èyí. Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ ìkórìíra yín sì pọ̀ gan an ni. A ka àwọn wòlíì sí òmùgọ̀, a ka ẹni ìmísí sí asínwín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.