Hosea 8:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítorí Efraimu ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un
Hosea 8:11 in English
Hosea 8:11 · Berean Standard Bible
Though Ephraim multiplied the altars for sin, they became his altars for sinning.
Context
9Nítorí pé wọ́n ti gòkè lọ sí Asiria
gẹ́gẹ́ bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tó ń rìn kiri.
Efraimu ti ta ara rẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀. 10Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárín Orílẹ̀-èdè,
Èmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsin yìí.
Wọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànù
lọ́wọ́ ìnilára ọba alágbára. 11“Nítorí Efraimu ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀
gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un 12Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn,
ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì. 13Wọ́n ń rú ẹbọ tí wọ́n yàn fún mi,
wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀,
ṣùgbọ́n inú Olúwa kò dùn sí wọn.
Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọn
yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Wọn yóò padà sí Ejibiti.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.