Hosea 2:21
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí; “Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùn àwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn;
Hosea 2:21 in English
Hosea 2:21 · Berean Standard Bible
“On that day I will respond—” declares the LORD— “I will respond to the heavens, and they will respond to the earth.
Context
19Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé;
Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti òtítọ́,
ní ìfẹ́ àti àánú. 20Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní òtítọ́
ìwọ yóò sì mọ Olúwa. 21“Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà,”
ni Olúwa wí;
“Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùn
àwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn; 22ilẹ̀ náà yóò sì dá ọkà,
wáìnì tuntun àti òróró lóhùn
Gbogbo wọn ó sì dá Jesreeli lóhùn. 23Èmi ó sì gbìn ín fún ara mi lórí ilẹ̀ náà,
Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí kò tì í ri ‘Àánú gbà.’
Èmi yóò sọ fún àwọn tí ‘Kì í ṣe ènìyàn mi pé,’
‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi’; àwọn náà yóò sì wí pé, ‘Ìwọ ni Ọlọ́run mi.’ ”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.