Hosea 2:20
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní òtítọ́ ìwọ yóò sì mọ Olúwa.
Hosea 2:20 in English
Hosea 2:20 · Berean Standard Bible
And I will betroth you in faithfulness, and you will know the LORD.”
Context
18Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú
fún wọn àti àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti
àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀.
Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́.
Ọfà, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà
kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu. 19Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé;
Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti òtítọ́,
ní ìfẹ́ àti àánú. 20Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní òtítọ́
ìwọ yóò sì mọ Olúwa. 21“Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà,”
ni Olúwa wí;
“Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùn
àwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn; 22ilẹ̀ náà yóò sì dá ọkà,
wáìnì tuntun àti òróró lóhùn
Gbogbo wọn ó sì dá Jesreeli lóhùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.