Hosea 2:16
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò pè mí ní ‘ọkọ mi’; ìwọ kò sì ní pè mí ní ‘olúwa à mi mọ́,’ ni Olúwa wí.
Hosea 2:16 in English
Hosea 2:16 · Berean Standard Bible
In that day,” declares the LORD, “you will call Me ‘my Husband,’* and no longer call Me ‘my Master.’*
Context
14“Nítorí náà, èmi yóò tàn án,
Èmi ó sì mú u lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀,
Èmi ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀ 15Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un,
Èmi yóò fi àfonífojì Akori ṣe ìlẹ̀kùn ìrètí fún un.
Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Ejibiti. 16“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,
ìwọ yóò pè mí ní ‘ọkọ mi’;
ìwọ kò sì ní pè mí ní ‘olúwa à mi mọ́,’
ni Olúwa wí. 17Èmi yóò mú orúkọ, àwọn òrìṣà Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀;
ìwọ kò sì ní rí orúkọ òrìṣà Baali pè mọ́. 18Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú
fún wọn àti àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti
àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀.
Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́.
Ọfà, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà
kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.