Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò mú orúkọ, àwọn òrìṣà Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀; ìwọ kò sì ní rí orúkọ òrìṣà Baali pè mọ́.

Hosea 2:17 in English

Hosea 2:17 · Berean Standard Bible

For I will remove from her lips the names of the Baals; no longer will their names be invoked.

Context

15Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un, Èmi yóò fi àfonífojì Akori ṣe ìlẹ̀kùn ìrètí fún un. Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Ejibiti. 16“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò pè mí ní ‘ọkọ mi’; ìwọ kò sì ní pè mí ní ‘olúwa à mi mọ́,’ ni Olúwa wí. 17Èmi yóò mú orúkọ, àwọn òrìṣà Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀; ìwọ kò sì ní rí orúkọ òrìṣà Baali pè mọ́. 18Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú fún wọn àti àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀. Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́. Ọfà, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu. 19Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé; Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti òtítọ́, ní ìfẹ́ àti àánú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.