Hosea 13:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀bi Efraimu ni a tí ko jọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀.
Hosea 13:12 in English
Hosea 13:12 · Berean Standard Bible
The iniquity of Ephraim is bound up; his sin is stored up.
Context
10Níbo ni ọba rẹ gbé wà nísinsin yìí kí ó bá à le gbà ọ là?
Níbo ni àwọn olórí ìlú yín wà,
àwọn tí ẹ sọ pé,
‘Fún wa ní ọba àti ọmọ-aládé’? 11Nítorí èyí nínú ìbínú mi ni mo fún un yín ní ọba,
nínú ìbínú gbígbóná mi, mo sì mú un kúrò. 12Ẹ̀bi Efraimu ni a tí ko jọ
gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀. 13Ìrora bí obìnrin tó fẹ́ bímọ ti dé bá a,
ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọmọ tí kò lọ́gbọ́n,
nígbà tí àsìkò tó,
ó kọ̀ láti jáde síta láti inú. 14“Èmi yóò rà wọ́n padà kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú.
Èmi yóò rà wọ́n padà lọ́wọ́ ikú,
ikú, àjàkálẹ̀-ààrùn rẹ dà?
Isà òkú, ìparun rẹ dà?
“Èmi kò ní ṣàánú mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.