Hosea 13:14
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èmi yóò rà wọ́n padà kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú. Èmi yóò rà wọ́n padà lọ́wọ́ ikú, ikú, àjàkálẹ̀-ààrùn rẹ dà? Isà òkú, ìparun rẹ dà? “Èmi kò ní ṣàánú mọ́.
Hosea 13:14 in English
Hosea 13:14 · Berean Standard Bible
I will ransom them from the power of Sheol; I will redeem them from Death.* Where, O Death, are your plagues? Where, O Sheol, is your sting?* Compassion is hidden from My eyes.
Context
12Ẹ̀bi Efraimu ni a tí ko jọ
gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀. 13Ìrora bí obìnrin tó fẹ́ bímọ ti dé bá a,
ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọmọ tí kò lọ́gbọ́n,
nígbà tí àsìkò tó,
ó kọ̀ láti jáde síta láti inú. 14“Èmi yóò rà wọ́n padà kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú.
Èmi yóò rà wọ́n padà lọ́wọ́ ikú,
ikú, àjàkálẹ̀-ààrùn rẹ dà?
Isà òkú, ìparun rẹ dà?
“Èmi kò ní ṣàánú mọ́. 15Bí ó tilẹ̀ gbilẹ̀ láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀
afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yóò wá,
yóò fẹ́ wá láti inú aginjù
orísun omi rẹ̀ yóò gbẹ
kànga rẹ̀ yóò gbẹ
pẹ̀lú olè yóò fọ́ ilé ẹrù
àti gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀. 16Ará Samaria gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn,
nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run wọn.
Wọn ó ti ipa idà ṣubú;
a ó fọ́ àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀,
a ó sì la àwọn aboyún wọn nínú.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.